Ede


English English
አማርኛ Amharic
العربية Arabic
العربية - الأردن Arabic (Jordanian)
العربية التونسية Arabic (Tunisian)
Armenian Armenian
Sign Language American Sign Language
বাংলা Bengali (India)
भोजपुरी Bhojpuri
Bosanski Bosnian
မြန်မာဘာသာ Burmese
中文(繁體,香港) Cantonese (Traditional)
中文(简体) Chinese (Simplified)
中文(繁體) Chinese (Traditional)
Hrvatski Croatian
Français French
Deutsch German
ગુજરાતી Gujarati
Hausa Hausa
हिन्दी Hindi
Bahasa Indonesia Indonesian
Italiano Italian
日本語 Japanese
ಕನ್ನಡ Kannada
한국어 Korean
Кыргызча Kyrgyz
کوردی Kurdish
ພາສາລາວ Lao
𑒧𑒻𑒟𑒱𑒪𑒲 Maithili
മലയാളം Malayalam
मराठी Marathi
नेपाली Nepali
ଓଡ଼ିଆ Odia
فارسی Persian/Farsi
Polski Polish
Português Portuguese
ਪੰਜਾਬੀ Punjabi
ਪੰਜਾਬੀ (ਪੱਛਮੀ) Punjabi (Western)
Русский Russian
Română Romanian
Slovenščina Slovenian
Soomaali Somali
Español Spanish
Kiswahili Swahili
தமிழ் Tamil
తెలుగు Telugu
ไทย Thai
Türkçe Turkish
اردو Urdu
Tiếng Việt Vietnamese
Yorùbá Yoruba

Ọlọrun Nlo Awọn eniyan lasan


E káàbọ̀ sí ìkékọ̀ Zúme. Zúme jé ọ̀rọ̀ Gíríkì fún “ìwúkàrà.”

Jésù sọ fún wa pé Ìjọba Ọlọ́run dàbi obìnrin tí o mú íwọ́n “zúme” kékeré tí o fi sínú ìyẹ̀fun púpọ́.

Bí o ti ṣiṣẹ́ ìwúkàrà sínú àpòpọ̀, ó tàn títí gbogbo ìyẹ̀fun yóò fi wú jáde ní gerege.

Jésù ‘n fihàn wá pé ènìyàn lásán lè mú `nkan kékeré láti kó ipa nlá.
 
Ibi afẹ́ dé ni láti ṣe ohun tí Jésù sọ - láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ènìyàn lásán ni àyíká àgbáyé lo àwọn irinṣẹ́ kékeré láti kó ipa nlá ní ìjọba Ọlọ́run!
 
Àwọn ìlànà ìkẹ́hìn tí Jésù fún àwọn ọmọlẹ́hìn rẹ̀ rọrùn. Ó wí pé - Gbogbo agbára ní ọ̀run àti ní ayé ni a ti fún mi. Nítorínà – e lọ Ṣe Àwọn ọmọ-ẹ́hìn ní gbogbo orílẹ̀-èdè ké se ìrìbomi fún wọn ní orúkọ Baba, Ọmọ ati Ẹ̀mí Mímọ́, Kí e kọ́ wọn láti gbọ́ràn sí gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ, Èmi ó sì wà pẹ̀lu yín nígbàgbogbo - títí dé òpin ọjọ́-ayé.
 
Àṣẹ Jésù rọrùn - Ṣe àwọn ọmọ-ẹ̀hìn
 
Àwọn ìtọ́nisọ́nà rẹ̀ lórí bí o ṣe lè ṣe tí ó rọrùn - Ṣe àwọn ọmọ-ẹ̀hìn dé ibikíbi tí o bá lo.

  • Ṣe àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nípasẹ̀ ìrìbomi fúnwọn ní orúkọ Baba, Ọmọ àti Ẹ̀mí Mímọ́
  • Ṣe àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nípasẹ̀ kíkọ́ wọn láti sègbọràn sí gbogbo ohun tí ó pa láṣẹ.

Nítorínàà kíni àwọn ìgbésẹ̀ láti ṣe ọmọ-ẹ̀hìn?

  •  À ń ṣe àwọn ọmọ-ẹ̀hìn ní gbogbo ìgbà - ibikíbi tí a nlọ àti bí a ṣé nlọ
  •  Nígbàtí ẹnìkan pinnu láti tẹ̀lé Jésù - ó yẹ kí wọn se ìrìbomi
  • Bí wọn ṣe ńdàgbà - ó yẹ kí á kọ́ gbogbo ọmọ ẹ̀hìn bí ó ṣe lè gbọ́ràn sí ohun gbogbo tí Jésù pa láṣẹ.
     
    Níwọ̀n bí ọ̀kan nínú àwọn ohun tí o pa làṣẹ jé ṣe àwọn ọmọ-ẹ̀hìn, ìyẹn túmọ̀ sí pé gbogbo ọmọ-ẹ̀hìn tí ó tẹ̀lé Jésù ní láti kọ́ ẹ̀kọ́ bí ó ṣe lè ṣe àwọn ọmọ-ẹ̀hìn pẹ̀lú.
     
    Àwọn ọmọ-ẹ̀hìn wọ̀nyẹn ni láti se àwọn ọmọ-ẹ̀hìn. Àti àwọn ọmọ-ẹ̀hìn yẹn tí wọ́n se pàápàá tún ní láti ṣe àwọn ọmọ-ẹ̀hìn pẹ̀lú.
     
    Ìsọdipúpọ̀ ọmọ – ẹ̀hìn ní isẹ́ zúmè.
     
    Ó dàbi ìwúkàrà - ó ṣiṣẹ́ gbogbo nípasẹ̀ ìyẹ̀fun títí gbogbo ìyẹ̀fun yóò fi wú di nílá.
    Nígbàtí Jésù pàṣẹ láti lọ ṣé àwọn ọmọ-ẹ̀hìn, Ó tún ṣe ìlérí kan.
     
    Jésù sọ - Èmi yóò wà pẹ̀lu rẹ nígbàgbogbo. Pàápàá títí dé òpin ọjọ́-ayé.
     
    Gbogbo ọmọ-ẹ̀hìn Jésù yẹ kí ó gbẹ́kẹ̀lé ìlérí pé Jésù wà pelú wa nígbàgbogbo. Nítorípé Ó wà!
     
    Ṣùgbọ́n ìyẹn tún túmọ̀ sí wípé gbogbo ọmọ-ẹ̀hìn Jésù ni láti faramó òtítọ́ wípé Jésù fẹ́ kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wá ṣe ọmọ-ẹ̀hìn. Nítorípé Ó se bẹ́ẹ̀.
     
    Jésù sọ - Gbogbo agbára ní ọ̀run àti ní ayé ni a ti fún mi. Nítorínà lọ kí o sì ṣe àwọn ọmọ-ẹ̀hìn.
     
    Àṣẹ tí Jésù gbẹ́kẹ̀lé nígbà tí Ó rán wa - jé àṣẹ rẹ̀.
     
    Jésù sọ pé kò sí àṣẹ tí ó ga jù èyí lọ. Kò sí àṣà kankan tí ó ní àṣẹ síi.
     
    Kò sí àṣà tí ó ní àṣẹ díẹ̀ síi. Kò sí òfin lórí ilé ayé tí ó ní àṣẹ díẹ̀ síi.
     
    Jésù sọ pé - Lọ se àwọn ọmọ-ẹ̀hìn.
     
    Àti gẹ́gẹ́ bi Zúmè - bí ìwúkàrà - a yóò ma lo láti tẹ̀síwájú àti dàgb̀a títí gbogbo iṣ́ẹ yóò ṣe.